Ijewo Igbagbo {Creed in Yoruba} by Daniel Ebhomien — Lyrics

Daniel Ebhomien Yoruba Creed (I believe) Solfa notation

Full Lyrics

CHORUS Mo gba Ọlọrun kan ṣoṣo gbọ. VERSE 1 Baba Olodumare ẹni ti o da ọrun oun aye, Ati ohun gbogbo ti a n ri ati eyi ti a ko ri. Ẹni kan ṣoṣo Ti i ṣe Jesu Kristi, Ẹni ti Baba ti bi siwaju ibẹrẹ aye gbogbo. Ọlọrun latinu Ọlọrun wa, imọlẹ latinu imọlẹ. VERSE 2 Ọlọrun tootọ latinu Ọlọrun tootọ, Ẹni ti a bi Ṣugbọn ti a ko da, Ti o ni iwa kan naa pẹlu Baba, Ti a si tipa Rẹ, da ohun gbogbo. Ẹni ti o to'ri awa eniyan ati igbala wa, Sọkalẹ lati ọrun wa. VERSE 3 Ti o si gba'ra eniyan lati inu Maria wundia, Nipa agbara Ẹmi mimọ ti a A kan an mọ agbelebu nitori wa: O jiya iku lẹwọ Pontiu Pilatu, a si sin, Ni ọjọ kẹta o jinde gẹgẹ bi Iwe mimọ ti wi, O si goke re ọrun o jokoo lọwọ ọtun Baba, VERSE 4 Yoo si tun pada pẹlu ogo lati da aaye oun oku lẹjọ, Ijọba Rẹ ki yoo si ni ipẹkun. Mo si gba Ẹmi Mimọ gbọ, Oluwa ati Olufunni ni iye. Ẹni ti o ti ọdọ Baba ati Ọmọ jade wa. Ti a jọ pe Oun pẹlu Baba ati Ọmọ ni a n fi ibọ fun Ti a si n yin ni ogo, ti o ti ẹnu awọn Wolii sọrọ VERSE 5 Mo si gba ijọ eniyan Ọlọrun kan ṣoṣo gbọ Ti o jẹ mimọ, Katoliki ati Apostoliki Mo jẹwọ ibatisi kan ṣoṣo fun imukuro ẹṣẹ Mo si n reti ajinde awọn oku, ati iye aye ti'n bọ wa. CODA Amin, Amin, Amin, Amin O.

Download the sheet music

Ijewo Igbagbo {Creed in Yoruba}

Ijewo Igbagbo {Creed in Yoruba}

By Daniel Ebhomien
Solfa
Yoruba
2 pages
7 Downloads
Creed (I believe)
0 0

More lyrics you may want