OGO, OGO O! {GLORIA IN YORUBA} by Oluwafemi Mathias O — Lyrics

Oluwafemi Mathias O Yoruba Gloria Mass Settings Solfa notation

Full Lyrics

CHORUS Ògo, Ògo O! Ògo, Ògo ni f'Ọlọ́run l'ókè Ọ̀run. Ògo, Ògo O! Ògo ni f'Ọlọ́run l'ókè Ọ̀run. Ògo, Ògo O! Ògo ni f'Ọlọ́run l'ókè Ọ̀run. VERSE 1 Àlàáfíà fún ẹ̀dá ayé O; f'àwọn ènìyàn, t'ó ní fẹ́ inú rere; Àwa yìn Ọ́ Bàbá, A fi bùkún fún Ọ; Àwọn foríbalẹ̀, A ń yìn Ọ́ lógo; Àwa ń dúpẹ́ fún Ògo ńlá rẹ; Ògo, Ògo, Ògo O! REFRAIN Ògo ni f'Ọlọ́run l'ókè Ọ̀run. VERSE 2 Bàbá Olódùmarè, Olúwa Ọba Ọ̀run; Jésù Kírísítì, Ọmọ bíbí rẹ̀ nìkan ṣoṣo; Ọ̀dọ́ Àgùntàn, t'ó ń kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ; Dákun ṣàánú, ṣàánú fún wa; Ògo, Ògo, Ògo O! VERSE 3 Ìwọ t'ó ń ti ń kó, t'ó ń kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ; Gbàdúrà tiwa, fétí s'ádùrá wa; Ìwọ t'ó jókòó l'ọ́wọ́ ọ̀tún Bàbá Olódùmarè; Ìwọ nìkan ni Mímọ́, àt'Olúwa; Pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, Nínú Ògo Ọlọ́run; Ògo, Ògo, Ògo O! ENDING Àmín, Àmín, Àṣẹ kó ṣẹ, Àmín, Àmín, Àṣẹ kó ṣẹ, Àmín, Àmín, Àṣẹ kó ṣẹ, Àmín, Àmín, Àṣẹ! Àmín.

Download the sheet music

OGO, OGO O! {GLORIA IN YORUBA}

OGO, OGO O! {GLORIA IN YORUBA}

By Oluwafemi Mathias O
Solfa
Yoruba
2 pages
3 Downloads
Gloria Mass Settings
0 0

More lyrics you may want